Luke 18:35-43

Afọ́jú alágbe gba ìwòsàn

35 aBí ó ti súnmọ́ Jeriko, afọ́jú kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà ó ń ṣagbe: 36Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó béèrè pé, kín ni ìtumọ̀ èyí. 37Wọ́n sì wí fún un pé, “Jesu ti Nasareti ni ó ń kọjá lọ.”

38Ó sì kígbe pé, “Jesu, ìwọ ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”

39Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, “Ìwọ Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”

40Jesu sì dúró, ó ní, kí á mú un tọ òun wá nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn, ó bi í, 41Wí pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ?”

Ó sì wí pé, “Olúwa jẹ́ kí èmi ríran.”

42 bJesu sì wí fún un pé, “Ríran; ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.” 43Lójúkan náà ó sì ríran, ó sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo àti gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run.

Copyright information for YorBMYO